Ẹ́sírà 1:1-6 BMY

1 Ní ọdún kìn-ní-ní Ṣáírúsì, ọba Páṣíà, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremáyà sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Ṣáírúsì ọba Páṣíà sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbégbé ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:

2 Èyí ni ohun tí Sáírúsì ọba Páṣíà wí pé: Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa fún un ní Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà.

3 Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà, láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ọlọ́run tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.

4 Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lù ú bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù.

5 Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù.

6 Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.