1 Nígbà náà ni ọba Dáríúsì pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí-nǹkan-pamọ́-sí ní ilé ìṣúra ní Bábílónì.
2 A rí ìwé kíká kan ní Ékíbátanà ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódí agbégbé Médíà, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀:Ìwé ìrántí:
3 Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Ṣáírúsì, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù:Jẹ́ kí a tún tẹ́ḿpìlì ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní gíga àti àádọ́rùn-ún (90) ẹsẹ̀ bàtà ní fífẹ̀,
4 pẹ̀lú ìpele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ìpele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.
5 Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadinésárì kó láti ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù tí ó sì kó lọ sí Bábílónì, di dídá padà sí àyè wọn nínú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.
6 Nítorí náà, kí ìwọ, Táténíà Baálẹ̀ agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà, kúrò níbẹ̀.
7 Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì díi lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí Baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbààgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.
8 Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbààgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí:Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Yúfúrátè kí iṣẹ́ náà má bà dúró.
9 Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn akọ ọ̀dọ́ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn fún ọrẹ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, ìfiyàn bí àwọn àlùfáà ní Jérúsálẹ́mù ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láì yẹ̀.
10 Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀:
11 Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a si fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.
12 Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀ èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹ́ḿpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣubú.Èmi Dáríúsì n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímú ṣẹ láì yí ohunkóhun padà.
13 Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dáríúsì pa, Táténáì, Baálẹ̀ ti agbégbé Yúfúrátè, àti Ṣétarì-Bóṣénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn pa á mọ́ láì yí ọ̀kan padà.
14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà Júù tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, ìran Ídò. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti àwọn àṣẹ Ṣáírúsì, Dáríúsì àti Aritaṣéṣéṣì àwọn ọba Páṣíà pọ̀.
15 A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Ádárì (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dáríúsì.
16 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—àwọn ìkógun, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.
17 Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́run mẹ́rin akọ ọ̀dọ́ àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, obúkọ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
18 Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpínsọ́wọ́ àti àwọn Léfì sì ẹgbẹẹgbẹ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè.
19 Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá.
20 Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Léfì pa ọ̀dọ́ àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn.
21 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
22 Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ Búrẹ́dì tí kò ní Yíìsìtì pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Ásíríà padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.