Ẹ́sírà 8 BMY

Olórí Àwọn Ìdílé Tí ó Padà Pẹ̀lú Ẹ́sírà

1 Wọ̀nyí ni àwọ̀n olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi làti Bábílónì ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba:

2 Nínú àwọn ọmọ Fínéhásì, Gásómù;nínú àwọn ọmọ Ítamárì, Dáníẹ́lì;nínú àwọn ọmọ Dáfídì, Hátúsì,

3 nínú àwọn ọmọ Ṣekaníáyà;nínú àwọn ọmọ Párósì, Ṣekaríáyà, àti pé àádọ́jọ (150) ọkùnrin fi orùkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;

4 nínú àwọn ọmọ Pahati-Móábù, Elehóénáyì ọmọ Seraíyà àti àwọn igba (200) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

5 nínú àwọn ọmọ Ṣátù, Ṣekaníáyà ọmọ Jahasíélì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

6 nínú àwọn ọmọ Ádínì, Ébédì ọmọ Jónátanì, àti àádọ́ta (50) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

7 nínú àwọn ọmọ Élámù, Jésáíyà ọmọ Ataláyà àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

8 nínú àwọn ọmọ Ṣéfátayà, Ṣébádáyà ọmọ Míkẹ́lì, àti ọgọ́rin (80) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

9 nínú àwọn ọmọ Jóábù, Ọbádáyà ọmọ Jéhíélì àti ogun-ó-lugba-ó-din méjì (218) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

10 nínú àwọn ọmọ Bánì, Ṣélómútì ọmọ Jósífáyà àti ọgọ́jọ 160 ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

11 nínú àwọn ọmọ Bébáì, Sakaráyà ọmọ Bébáì àti ọkúnrin 45 méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀;

12 nínú àwọn ọmọ Ásígádì, Johánánì ọmọ Hákátanì, àti àádọ́fà (110) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

13 nínú àwọn ọmọ Ádóníkámù, àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orùkọ wọn ń jẹ̀ Élífélétì, Jéúélì àti Ṣémáyà, àti ọgọ́ta (60) ọkúnrin pẹ̀lú wọn;

14 Nínú àwọn ọmọ Bígífáyì, Hútayì àti Ṣákúrì, àti àádọ́rin 70 ọkúnrin pẹ̀lú wọn.

Ìpadà Sí Jérúsálẹ́mù

15 Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń ṣàn lọ sí Áháfà, a pàgọ́ síbẹ̀ fùn odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárin àwọn ènìyàn àti àárin àwọn àlùfáà, ń kò ri ọmọ Léfì kankan níbẹ̀.

16 Nígbà náà ni mo pe Élíásérì, Áríélì, Ṣemanáyà, Elinátanì, Járíbù, Elinátánì, Nátanì, Ṣakaráyà, àti Mésúlámù, ti wọ̀n jẹ̀ olórí, àti Jóíáríbù àti Elinátanì ti wọ̀n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,

17 mo rán wọn sí Ídò, tí ó wà ní ibi ti a ń pè ni Kásífíà, mo sì sọ ohun ti wọn yóò sọ fun Ídò àti àwọn arakunrin rẹ̀ ti wọn jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì ní Kásífíà fún wọn, pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá fún wa fún ilé Ọlọ́run wa.

18 Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣérébáyà wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ìran Máhílì ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Ṣérébáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìlélógún (18).

19 Àti Ásábáyà, pẹ̀lú Jésáíyà láti ìran Mérárì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún (20) ọkùnrin.

20 Wọ́n sì tún mú ọ̀kànlénígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì wá-àwọn ènìyàn tí Dáfídì àti àwọn ìjòyè rẹ gbé kalẹ̀ láti ràn àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

21 Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Áháfà, mo kéde ààwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa.

22 Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹsin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbìnú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ sílẹ̀.”

23 Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.

24 Nígbà náà ni mo yà àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣérébáyà, Hásábáyà àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn,

25 Mo sì fi òṣùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀, awọn ìjòyè àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ gbe fi sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa.

26 Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀talẹ̀láàdọ́ta (650) talẹ́ńtì sílifà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn ún talẹ́ńtì, talẹ́ńtì wúrà

27 ogún (20) bóòlù wúrà (kílòmítà mẹ́jọ ààbọ̀) tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dárìkì, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí, bí i wúrà.

28 Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohum èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Sílífà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín.

29 Tọ́jú wọn dáradára títí ìwọ yóò se fi òṣùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jérúsálẹ́mù ní iwájú àwọn aṣáájú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Ísírẹ́lì.”

30 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ ti a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jérúsálẹ́mù.

31 Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Áháfà láti lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa.

32 Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nibi ti a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta.

33 Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Mérémótì ọmọ Úráyà lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Élíásérì ọmọ Fínéhásì wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì Jósábádì ọmọ Jésíúà àti Núádáyà ọmọ Bínúì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

34 Gbogbo nǹkan ni a kà tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ìgbà náà.

35 Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí o ti pada láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, àádọ́rùn-ún-o-lé-mẹ́ta akọ ọdọ àgùntàn àti òbúkọ méjìlá fún ọrẹ sísun sí Olúwa.

36 Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Éúfúrétè, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run nígbà náà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10