Ẹ́sírà 7 BMY

Ésírà Wá Sí Jérúsálẹ́mù

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì ní Páṣíà, Ẹ́sírà ọmọ Ṣéráíyà, ọmọ Ásáríyà, ọmọ Hílíkíyà,

2 Ọmọ Ṣálúmù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Áhítúbì,

3 ọmọ Ámáríyà, ọmọ Ásáríyà, ọmọ Méráíótù,

4 ọmọ Ṣéráháyà, ọmọ Húsì, ọmọ Búkì,

5 ọmọ Ábísúà, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élíásérì, ọmọ Árónì olórí àlùfáà—

6 Ẹ́sírà yìí gòkè wá láti Bábílónì. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfìn Mósè, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀.

7 Ní ọdún keje ọba Aritaṣéṣéṣì díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì náà gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù.

8 Ní oṣù kánùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Ẹ́sírà dé sí Jérúsálẹ́mù.

9 Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Bábílónì ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀.

10 Ẹ́sírà ti fi ara rẹ̀ jìn fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mósè ní Ísírẹ́lì.

Ọba Aritaṣéṣéṣì Kọ Lẹ́tà Sí Ẹ́sírà

11 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́ta ti ọba Aritaṣéṣéṣì fún àlùfáà Ẹ́sírà olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Ísírẹ́lì:

12 Aritaṣéṣéṣì, ọba àwọn ọba,Sí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ni òfin Ọlọ́run ọ̀run:Àlàáfíà.

13 Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkòóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jérúsálẹ́mù lè tẹ̀lé ọ lọ.

14 Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèjè rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

15 Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù,

16 pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Bábílónì àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run wọn ní Jérúsálẹ́mù.

17 Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ (ọkà), àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ ní Jérúsálẹ́mù.

18 Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tó kù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín.

19 Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jérúsálẹ́mù fún ìsìn nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ.

20 Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.

21 Èmi, ọba Aritaṣéṣéṣì, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Yúfúrátè láìrójú láti pèṣè ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín

22 tó ọgọ́run kan talẹ́ntì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n jéró, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù wáìnì, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù òróró olífì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.

23 Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbégbé ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀?

24 Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sisán owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí.

25 Ìwọ Ẹ́sírà, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè—Yúfúrátè—gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà.

26 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.

27 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọla wá sí ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù ní ọ̀nà yìí.

28 Ẹni tí ó jẹ́ kí ojú rere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10