6 Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.
7 Ní àfikún, ọba Ṣáírúsì mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadinésárì ti kó lọ láti Jérúsálẹ́mù tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀.
8 Ṣáírúsì ọba Páṣíà pàṣẹ fún Mítúrédátì olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣéṣíbásárì ìjòyè Júdà.
11 Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn ún-ó-lé-irinwó (5,400). Ṣéṣíbáṣárì kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Bábílónì sí Jérúsálẹ́mù.