1 Nígbà tí Ẹ́sirà ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sunkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lí ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sunkún kíkorò.
2 Nígbà náà ni Ṣékáníáyà ọmọ Jéhíélì, ọ̀kan lára ìran Élámù, sọ fún Ẹ́sírà pé, Àwa ti jẹ́ aláìsọ̀ọ́tọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrin àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Ísírẹ́lì
3 Ní sinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Ẹ́sírà Olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin.
4 Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.