1 Wàyí o, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Júdà tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrin àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà. Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀,
62 Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
64 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ (42,360) ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-òjìdínnírinwó.
65 Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.
66 Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbaka òjìlélúgba-ó-lé-márùn-ún (245)
67 Ràkúnmí jẹ́ irinwó-ó-lé-márùndínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rínlélọ́gbọ̀n-ó-dín-ọgọ́rin (6,720).
68 Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá silẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.