62 Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
64 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ (42,360) ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-òjìdínnírinwó.
65 Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.
66 Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbaka òjìlélúgba-ó-lé-márùn-ún (245)
67 Ràkúnmí jẹ́ irinwó-ó-lé-márùndínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rínlélọ́gbọ̀n-ó-dín-ọgọ́rin (6,720).
68 Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá silẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.
69 Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dírámà wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.