Ẹ́sírà 3:1-7 BMY

1 Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jérúsálẹ́mù.

2 Nígbà náà ni Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run

3 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n ṣíbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ọrẹ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.

4 Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àpèjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ọrẹ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

5 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti-gbà-dé-gbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa.

6 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ọrẹ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.

7 Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Ṣídónì àti Tírè, kí wọ́n ba à le è kó igi Sídà gba ti orí omi òkun láti Lébánónì wá sí Jópà, gẹ́gẹ́ bí Sáírúsì ọba Páṣíà ti pàṣẹ.