12 Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jérúsálẹ́mù wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.
13 Ṣíwájú síi, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù.
14 Nísinsìn yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba,
15 kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn àṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò ríi wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oní wàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run.
16 A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbégbé Yúfúrátè.
17 Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà:Sí Réhúmì balógun, Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yóòkù tí ń gbé ní Samáríà àti ní òpópónà Yúfúrátè:Ìkíní.
18 A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.