10 Ẹ́sírà ti fi ara rẹ̀ jìn fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mósè ní Ísírẹ́lì.
11 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́ta ti ọba Aritaṣéṣéṣì fún àlùfáà Ẹ́sírà olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Ísírẹ́lì:
12 Aritaṣéṣéṣì, ọba àwọn ọba,Sí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ni òfin Ọlọ́run ọ̀run:Àlàáfíà.
13 Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkòóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jérúsálẹ́mù lè tẹ̀lé ọ lọ.
14 Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèjè rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù.
15 Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù,
16 pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Bábílónì àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run wọn ní Jérúsálẹ́mù.