10 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa kò pa àṣẹ rẹ mọ́
11 èyí tí ìwọ fún wa láti ipaṣẹ̀ àwọn wòlíì ìrànṣẹ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé ilẹ̀ ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó di àìmọ̀ pẹ̀lú ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn rẹ, nípa ṣíṣe ohun ìríra ilẹ̀ náà ti kún fún ohun àìmọ́ láti igun kan dé ìkejì.
12 Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbà-kí-gbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì jẹ ohun dáradára ilẹ̀ náà, kí ẹ sì fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayé rayé;
13 Ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí wa jẹ́ ayọrísí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi-ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, ṣíbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó sẹ́kù bí èyí.
14 Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnìkẹ́ni tí yóò là?
15 Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìwọ jẹ́ olódodo O dá wa sí lónìí bí àwọn tí ó ṣẹ́kà. Àwa nìyí níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí rẹ̀ ẹyọ ẹnìkan kò lè dúró níwájú rẹ.