6 Mo sì gbàdúrà:Ọlọ́run mi, ojú tì mí gidigidi kò sì yá mi lórí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹṣẹ̀ wá ga ju orí wa lọ, àwọn àìṣedéédéé wa sì ga kan àwọn ọ̀run.
7 Láti ìgbà àwọn baba wá, títí di ìsinsin yìí, àìṣedéédéé wa ti pọ̀ jọjọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà àti ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀ṣín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.
8 Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, Olúwa Ọlọ́run ti fi àánú rẹ̀ dá àwa tí ó sẹ́kù sí tí ó sì fún wa ni ibi pàtàkì nínú ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí náà Ọlọ́run wa ti fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú wa àti ìgbé ayé túntún kúrò nínú ìgbékùn wa.
9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Páṣíà: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntún láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ mọ, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù.
10 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa kò pa àṣẹ rẹ mọ́
11 èyí tí ìwọ fún wa láti ipaṣẹ̀ àwọn wòlíì ìrànṣẹ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé ilẹ̀ ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó di àìmọ̀ pẹ̀lú ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn rẹ, nípa ṣíṣe ohun ìríra ilẹ̀ náà ti kún fún ohun àìmọ́ láti igun kan dé ìkejì.
12 Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbà-kí-gbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì jẹ ohun dáradára ilẹ̀ náà, kí ẹ sì fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayé rayé;