3 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hágáì wí pé:
4 “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fún ra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀sọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”
5 Ní sinsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsí ọ̀nà yín.
6 Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; Ẹ̀yin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”
7 Báyìí ni Olúwa alágbára wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.
8 Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà leè dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí.
9 “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsíi,, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dáhoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.