Jóẹ́lì 3 BMY

A Dá Orilẹ Èdè Lẹ́jọ́

1 “Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, àti ní àkókò náà,nígbà tí èmi tún mú ìgbékùn Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà bọ̀.

2 Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀ èdè jọpẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jéhóṣáfátì.Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,àti nítorí Ísírẹ́lì ìní mi,tí wọ́n fọ́nká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè,wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.

3 Wọ́n si ti di ibò fún àwọn ènìyàn mi;wọ́n sì ti fi ọmọdé-kùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,wọ́n sì ta ọmọdé bìnrin kan fúnọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

4 “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tirè àti Ṣídónì, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Fílístínì? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹyín ṣe padà sórí ara yín.

5 Nítorí tí ẹ̀yín tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere daradara mi lọ sínú tẹ́ḿpìlì yín.

6 Àti àwọn ọmọ Júdà, àti àwọn ọmọ Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ara Gíríkì, kí ẹ̀yin báà le sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìnì wọn.

7 “Kíyèsì í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.

8 Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Júdà, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Ṣábíà, fún orílẹ̀ èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.

9 Ẹ kéde èyí ní àárin àwọn aláìkọlà;Ẹ dira ogun,ẹ jí àwọn alágbára,Jẹ kí awọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun,

10 Ẹ fi irin itulẹ yín rọ idà,àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.Jẹ́ kí aláìlera wí pé,“Ara mi le koko.”

11 Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà láti gbogbo àyíká,kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri:Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ ṣọkalẹ̀, Olúwa.

12 “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojìJéhóṣáfátì ẹ̀yin aláìkọlà:nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jòkòó láti ṣeìdájọ́ àwọn aláìkọlà yí kákìri.

13 Ẹ tẹ̀ dòjé bọ̀ ọ́,nítorí ìkórè pọ́n:ẹ wá, ẹ ṣọ̀kalẹ̀;nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọnọpọ́n kún-à-kún-wọ́sílẹ̀nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”

14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ní àfonífojì ìdájọ́,nítorí ọjọ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ní àfonífojì ìdájọ́.

15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.

16 Olúwa yóò sí ké ramúramú láti Ṣíónì wá,yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jérúsálẹ́mù wá;àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtìṢùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,àti agbára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ìbùkún Fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run

17 “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,tí ń gbé Ṣíónì òkè mímọ́ mi.Ìgbà náà ni Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ mímọ́;àwọn àlejò kì yóò sì kó o mọ́.

18 “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè-ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa ṣàn fún wàrà;gbogbo odò Júdà tí ó gbẹ́ yóò máa ṣàn fún omi.Oríṣun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ile Olúwa wá,yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣítímù.

19 Ṣùgbọ́n Éjíbítì yóò di ahoro,Édómù yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Júdà,ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

20 Ṣùgbọ́n Júdà yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,àti Jérúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.

21 Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tíì wẹ̀nù.Nítorí Olúwa ń gbé Síónì.”

orí

1 2 3