Jónà 1:3-9 BMY

3 Ṣùgbọ́n Jónà dìde kúrò láti sá lọ sí Tásísì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Jópà, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tásísì: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tásísì kúrò níwájú Olúwa.

4 Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú òkun, ìjì líle sì wà nínú òkun tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́.

5 Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́.Ṣùgbọ́n Jónà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra.

6 Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóorun? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.”

7 Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jónà.

8 Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?”

9 Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Hébérù ni èmi, mo sì bẹ̀rù Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.”