12 Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì tò ègé ẹran náà, orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.
13 Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa
14 “ ‘Bí ọrẹ tí a fẹ́ fi fún Olúwa bá jẹ́ ti àwọn ẹyẹ, kí ó mú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé
15 Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.
16 Kí ó yọ àjẹsí (àpò oúnjẹ) ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà
17 Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má yaá tan pátapáta. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ọrẹ ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa.