Léfítíkù 14 BMY

Ìwẹ̀nùmọ́ Kúrò Nínú Àrùn Ẹ̀tẹ̀ Tó Mú Awọ Ara

1 Olúwa sọ fún Mósè pé,

2 “Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú-un tọ àlùfáà wá.

3 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú àrùn ẹ̀tẹ̀ náà.

4 Kí àlùfáà páṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.

5 Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀.

6 Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà.

7 Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò nínú àrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ níta gbangba.

8 “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.

9 Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ kéje: irun orí rẹ̀, irungbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tó kù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.

10 “Ní ọjọ́ kejọ kí ó mú àgbò méjì àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n òróró kan.

11 Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́: yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá ṣíwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

12 “Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹbí. Kí ó sì fí wọn níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífí.

13 Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ nibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.

14 Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀ mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

15 Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.

16 Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje.

17 Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀ mọ́.

18 Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀ mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.

19 “Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀: yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun.

20 Yóò sì rú u lórí pẹpẹ pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, yóò sì ṣe ètùtù fún un: Òun yóò sì di mímọ́.

21 “Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹbí, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òṣùwọ̀n òróró

22 àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.

23 “Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ ṣíwájú àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa.

24 Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́ àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì.

25 Kí ó pa ọ̀dọ́ àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún.

26 Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ osì ara rẹ̀.

27 Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa.

28 Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹṣẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí.

29 Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún: láti ṣe ètùtù fún un ní ìwájú Olúwa.

30 Lẹ́yìn náà kí ó fí àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rúbọ níwọn ti agbára rẹ̀ mọ.

31 Ọ̀kan fún ẹbọ ẹṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ: Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ìpò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.”

32 Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.

Ìwẹ̀nùmọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀tẹ̀ Ní Inú Ilé

33 Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé.

34 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kénánì tí mo fi fún yín ni ìní, tí mo sì fí àrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ile kan ní ilẹ̀ ìní yín.

35 Kí ẹni tí ó ní ilọ̀ náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ àrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’

36 Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má báà di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.

37 Yóò yẹ àrùn náà wò, bí àrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.

38 Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ilẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.

39 Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí àrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.

40 Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí àrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú.

41 Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà.

42 Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.

43 “Bí àrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.

44 Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.

45 Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

46 “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

47 Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48 “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí àrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé àrùn náà ti lọ.

49 Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi sídà òdòdó àti hísópù.

50 Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sorí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀.

51 Kí ó ri igi sídà, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ náà lẹ́ẹ̀méje.

52 Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi sídà, hisopu àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́.

53 Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”

54 Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyí àrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká (ẹ̀tẹ̀), fún làpálàpá,

55 fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, tàbí ilé,

56 fún ìwú, fún èélá àti ibi ara dídán.

57 Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́.Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún àrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27