Léfítíkù 20 BMY

Ìjìyà Fún Ẹ̀ṣẹ̀

1 Olúwa sọ fún Mósè pé,

2 “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún mólékì, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.

3 Èmi tìkarami yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà mólékì ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú.

4 Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà mólékì tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀.

5 Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ge wọn kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó dìjọ ṣe àgbérè tọ òrìṣà mólékì lẹ́yìn.

6 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbérè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

7 “ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

8 Ẹ máa kíyèsí àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́: Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

9 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé bàbá tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé bàbá àti ìyá rẹ̀.

10 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa.

11 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù bàbá rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

12 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

13 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n í ti bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

14 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyatọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má baà gbilẹ̀ láàrin yín.

15 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà.

16 “ ‘Bí obìnrin kan bá sún mọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa: ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn

17 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin bàbá rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí: Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn: ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀.

18 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá sún mọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láàyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn.

19 “ ‘Má ṣe bá arábìnrin bàbá tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòòhò ìbátan rẹ: Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín.

20 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin bàbá rẹ̀. A ó jẹ wọ́n ní ìyà; wọn yóò sì kú láìlọ́mọ.

21 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ.

22 “ ‘Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má baà pọ̀ yín jáde.

23 Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kóríra wọn.

24 Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn; Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.” Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn yòókù.

25 “ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrin ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrin ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́.

26 Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀ èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.

27 “ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrin yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27