1 Olúwa sọ fún Mósè pé
2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara ólífì wá láti fi tan iná, kí àtùpà lè máa jò láì kú.
3 Lẹ́yìn aṣọ títa tibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Árónì ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
4 Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá àtùpà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójojúmọ́.
5 “Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdáméjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹfà (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan.
6 Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fàmẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó gòólù bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.
7 Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ ọrẹ iná sísun fún Olúwa.
8 Búrẹ́dì yìí ni kí ẹ gbé wá ṣíwájú Olúwa nígbàkugbà, lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.
9 Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni ín. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”
10 Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Éjíbítì. Ó jáde lọ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrin òun àti ọmọ Ísírẹ́lì kan.
11 Ọmọkùnrin arábìnrin Ísírẹ́lì náà sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè: Wọ́n sì mú-un tọ Mósè wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Selomiti, ọmọbìnrin Débírì, ará Dánì).
12 Wọ́n fi í sínú àtìmọ́lé kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.
13 Olúwa sì sọ fún Mósè pé:
14 “Mú asọ̀rọ̀òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fi hàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.
15 Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọbíbí Ísírẹ́lì, bí ó bá ti sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.
17 “ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹmi ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á.
18 Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.
19 Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára: ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i.
20 Bí ó bá ṣẹ́ egungun ẹnìkan, egungun tirẹ̀ náà ni kí a ṣẹ́, bí ó bá fọ́ ojú ẹnìkan, ojú tirẹ̀ náà ni kí a fọ́, bí ó bá ká eyín ẹnìkan, eyín tirẹ̀ náà ni kí a ká. Bí ó ti pa ẹnìkejì lára náà ni kí ẹ pa òun náà lára.
21 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ọ̀sìn gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ni kí ẹ pa.
22 Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
23 Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́: wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mósè.