2 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.
3 “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ múu wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó bá à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa
4 kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un.
5 Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájù Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í se ọmọ Árónì yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.
6 Òun yóò bó àwọ ara akọ ọ̀dọ́ màlúù náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́.
7 Àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà.
8 Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò tò ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí ori igi tó ń jó lórí pẹpẹ.