17 “Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbégbé ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú Olúwa.
18 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ibi mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbégbé ibi mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ.”
19 Árónì sì dá Mósè lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún sẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?”
20 Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀.