4 Mósè pe Másáélì àti Élísáfánì ọmọ Yúsíélì tí í ṣe arákùnrin Árónì, ó sọ fún wọn pé “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.”
5 Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mósè ti sọ.
6 Mósè sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù, Élíásárì àti Ítamárì pé, “ẹ má ṣe sọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ sí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.
7 Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kùú, nítorí pé òróró ìtasórí Olúwa wà lórí yín” Wọ́n sì ṣe bí Mósè ti wí.
8 Olúwa sì sọ fún Árónì pé.
9 “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkigbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.
10 Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin mímọ́ àti àìmọ́, láàrin èérí àti àìléérí.