19 akọ, onírúurú oódẹ, atọ́ka àti àdán.
20 “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín
21 irú àwọn kòkòrò oníyẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le Jẹ nìyí: Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìsẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.
22 Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú esú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata.
23 Ṣùgbọ́n gbogbo kòkòrò oníyẹ́ yóòkù tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin ni kí ẹ kórìíra.
24 “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
25 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.