33 Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.
34 Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ kéje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara: tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́: Kí ó fọ aṣọ rẹ̀: òun yóò sì mọ́.
35 Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fi hàn pé ó ti mọ́.
36 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara; kí àlùfáà má ṣe yẹ irun pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ wò mọ́. Ẹni náà ti di aláìmọ́.
37 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdájọ́ àlùfáà pé ẹni náà kò mọ́, tí ojú làpálàpá náà kò bá yípadà, tí irun dúdú si ti hù jáde lójú rẹ̀. Làpálàpá náà ti san. Òun sì ti di mímọ́. Kí àlùfáà fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti di mímọ́.
38 “Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní ojú àpá funfun lára àwọ̀ ara rẹ̀.
39 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú àpá náà bá funfun àrùn ara tí kò léwu ni èyí tí ó farahàn lára rẹ̀: Ẹni náà mọ́