38 “Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní ojú àpá funfun lára àwọ̀ ara rẹ̀.
39 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú àpá náà bá funfun àrùn ara tí kò léwu ni èyí tí ó farahàn lára rẹ̀: Ẹni náà mọ́
40 “Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù tí ó sì párí. Ẹni náà mọ́.
41 Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù níwájú orí tí ó sì párí níwájú orí. Ẹni náà mọ́.
42 Ṣùgbọ́n bí ó bá ní egbò pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ní ibi orí rẹ̀ tí ó pá, tàbí níwájú orí rẹ̀: àrùn tí ń ràn ká iwájú orí tàbí ibi orí ni èyí.
43 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí egbò tó wù níwájú orí rẹ̀ tàbí tí orí rẹ̀ bá pupa díẹ̀ tí ó dàbí àrùn ara tí ń ràn kálẹ̀.
44 Alárùn ni ọkùnrin náà: kò sì mọ́, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ torí egbò tí ó wà ní orí rẹ̀.