41 Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù níwájú orí tí ó sì párí níwájú orí. Ẹni náà mọ́.
42 Ṣùgbọ́n bí ó bá ní egbò pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ní ibi orí rẹ̀ tí ó pá, tàbí níwájú orí rẹ̀: àrùn tí ń ràn ká iwájú orí tàbí ibi orí ni èyí.
43 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí egbò tó wù níwájú orí rẹ̀ tàbí tí orí rẹ̀ bá pupa díẹ̀ tí ó dàbí àrùn ara tí ń ràn kálẹ̀.
44 Alárùn ni ọkùnrin náà: kò sì mọ́, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ torí egbò tí ó wà ní orí rẹ̀.
45 “Kí ẹni tí àrùn náà wà ní ara rẹ̀ wọ àkísà. Kí ó má ṣe gé irun rẹ̀, kí ó daṣọ bo ìṣàlẹ̀ ojú rẹ̀ kí ó sì máa ké wí pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’
46 Gbogbo ìgbà tí àrùn náà bá wà ní ara rẹ̀; aláìmọ́ ni: kí ó máa dá gbé. Kí ó máa gbé lẹ́yìn ibùdó.
47 “Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá ba aṣọ kan jẹ́ yálà aṣọ onírun àgùtàn tàbí aṣọ funfun.