3 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú àrùn ẹ̀tẹ̀ náà.
4 Kí àlùfáà páṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.
5 Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀.
6 Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà.
7 Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò nínú àrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ níta gbangba.
8 “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.
9 Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ kéje: irun orí rẹ̀, irungbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tó kù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.