1 Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:
2 Ẹ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀: kí ẹ wí fún wọn pé: Bí ìṣunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara: ìṣunjáde náà jẹ́ àìmọ́.
3 Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìṣunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́.
4 “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìṣunjáde náà bá sùn di àìmọ́.
5 Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá joko lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀: kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.