1 Olúwa sọ fún Mósè lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Árónì méjèèje tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa.
2 Olúwa sì sọ fún Mósè pé “Kìlọ̀ fún Árónì arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí ibi mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má baà kú” nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.
3 Báyìí ni Árónì yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun.
4 Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í: yóò sì dé fìlà funfun: àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí: Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n.
5 Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n: àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.
6 Árónì yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀.