Léfítíkù 16:17-23 BMY

17 Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ ibi mímọ́ lọ láti ṣe ètùtù: títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnrarẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Ísírẹ́lì.

18 Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa: yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká.

19 Lẹ́yìn náà òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

20 Lẹ́yìn ti Árónì ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ: òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá.

21 Árónì yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Ísírẹ́lì lée lórí: gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí aṣálẹ̀ láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.

22 Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedédé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì tú ewúrẹ́ náà sílẹ̀ ní àṣálẹ́.

23 Árónì yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé yóò sì bọ́ aṣọ funfun gbòò tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀