Léfítíkù 17:3-9 BMY

3 Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Ísírẹ́lì bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó

4 tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

5 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá ṣíwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé: kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa.

6 Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa.

7 Torí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbérè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.

8 “Kí ó sọ fún wọn pé: ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Ísírẹ́lì tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn tí ó bá rú ọrẹ sísun tàbí ṣe ẹbọ

9 tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.