1 Olúwa sọ fún Mósè pé:
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
3 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Éjíbítì níbi tí ẹ ti gbé rí: bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kénánì níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé iṣe wọn.
4 Ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin mi kí ẹ sì kíyèsí àti pa àṣẹ mi mọ́.
5 Ẹ pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ṣe ìgbọ́ràn sí wọn yóò máa gbé nípa wọn, Èmi ni Olúwa.
6 “ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.
7 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.