33 “ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi
34 kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrin yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Éjíbítì rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
35 “ ‘Ẹ má ṣe lo òsùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òsùwọ̀n ọ̀pá, òsùwọ̀n ìwúwo tàbí òsùwọ̀n onínú.
36 Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì.
37 “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”