Léfítíkù 21:4-10 BMY

4 Nítorí tí ó jẹ́ olórí òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

5 “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irungbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fi hàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

6 Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má baà sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fí iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.

7 “ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀ sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.

8 Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.

9 “ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa sísọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó: ó dójú ti bàbá rẹ̀, a ó sun ún ní iná.

10 “ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ tí a sì ti fi amì òróró yàn láti máa wọ aṣọ àlùfáà, gbọdọ̀ tọ́jú irún orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.