32 Ọjọ́ ìsinmi ni fún yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”
33 Olúwa sọ fún Mósè pé,
34 “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún Àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.
35 Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́: ṣẹ kò gbọdọ̀ e iṣẹ́ ojúmọ́.
36 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojojúmọ́.
37 (“ ‘Ìwònyí ni àwon àjọ̀dún tí Olúwa ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i ìpàdé mímọ́ fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa wá—ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan:
38 Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)