41 Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀: Ẹ ṣe é ní oṣù keje.
42 Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọbíbí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́.
43 Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
44 Báyìí ni Mósè kéde àwọn àṣàyàn ọdún Olúwa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.