20 Ẹ le bèèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?”
21 Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀.
22 Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kejọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsàn-án yóò fi dé.
23 “ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni-ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àlejò àti ayálégbé,
24 Ní gbogbo orílẹ̀ èdè ìní yín, ẹ fi àyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.
25 “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá talákà, débi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà.
26 Ẹni tí kò ní ẹni tó lè ràápadà fún un, tí òun fúnrarẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.