29 “ ‘Bí arákùnrin kan bá ta ilẹ̀ tí ó wà nínú ìlú, ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á padà láàrin ọdún kan sí àkókò tí ó tà á.
30 Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrin ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrin ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátapáta fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.
31 Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.
32 “ ‘Àwọn ọmọ Léfì ní ẹ̀tọ́, nígbàkugbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Léfì.
33 Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Léfì ni ìní wọn láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì
34 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni.
35 “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá talákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó baà leè máa gbé láàrin yín.