18 “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí: Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
19 Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín: ojú ọ̀run yóò le koko bí irin: ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le).
20 Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.
21 “ ‘Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
22 Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárin yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.
23 “ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi.
24 Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú.