9 “ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ̀gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Olúwa, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún Olúwa di mímọ́.
10 Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára. Bí ó bá se bẹ́ẹ́ ti Olúwa ni ẹranko méjèèjì.
11 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ níti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún Olúwa. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà.
12 Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí. Iye owó náà ni kí ó jẹ́.
13 Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà: ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún.
14 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́.
15 Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀.