5 Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, kí ó sì gbé e lọ sínú àgọ́ ìpàdé.
6 Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa, níwájú aṣọ títa ibi mímọ́.
7 Àlùfáà yóò tún mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tùràrí tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé. Kí ó da gbogbo ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù tókù sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
8 Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ nínú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú àti gbogbo ohun tó so mọ́ wọn.
9 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú kíndìnrín.
10 Gẹ́gẹ́ bí a se ń yọ ọ̀rá kúrò lára màlúù tí a fi rúbọ àlàáfíà; àlùfáà yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.
11 Ṣùgbọ́n awọ màlúù àti gbogbo ara rẹ̀, àti ẹṣẹ̀, gbogbo nǹkan inú àti ìgbẹ́ rẹ̀.