21 Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéé-kèè-kéé bí òórùn dídùn sí Olúwa.
22 Ọmọkùnrin Árónì tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti Olúwa títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátapáta.
23 Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátapáta, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.”
24 Olúwa sọ fún Mósè pé:
25 “Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin: ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Olúwa níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
26 Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.
27 Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́.