24 Olúwa sọ fún Mósè pé:
25 “Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin: ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Olúwa níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
26 Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.
27 Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́.
28 Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi ṣe ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi ṣe é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára.
29 Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
30 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní ibi mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún.