2 “Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ mààlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀.
3 Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”
4 Mósè sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
5 Mósè sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ pé kí á ṣe.”
6 Nígbà náà ni Mósè mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá ṣíwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.
7 Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlékè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí.
8 Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Úrímù àti Júmímù síbi ìgbàyà náà.