10 Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!
11 Ètè rẹ ń kán dídùn afárá oyin, ìyàwó mi;wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lébánónì.
12 Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábinrin mi, ìyàwó miìṣun tí a sé mọ́, oríṣun tí a fi èdìdì dì.
13 Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pàmóńgánéètì niti òun ti àṣàyàn èso; kípírésì àti nádì,
14 Nádì àti Ṣáfírónì,kálámúsì àti kínámónì,àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,òjíá àti álóépẹ̀lú irú wọn.
15 Ìwọ ni ọgbà oríṣun, kànga omi ìyè,ìṣàn omi láti Lẹ́bánónì wá.
16 Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwákí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúṣù!Fẹ́ lórí ọgbà mi,kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.