11 Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le se ọkọ yin?
12 Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí mo ti lẹ̀ ní èrò wí pé ìrètí sì wà fún mi, tí mo sì fẹ́ ọkọ mìíràn lónìí tí mo sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn,
13 ṣé ẹ̀yin le è dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà láì fẹ́ ọkọ mìíràn nítorí wọn ni? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi ju bí ó ti jẹ́ fún ẹ̀yin lọ nítorí pé ọwọ́ Olúwa ti fìyà jẹ mi lọ́nà tó pamí lára gidi.”
14 Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún sunkún kíkorò. Nígbà náà ní Órípà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rúùtù dì mọ́ ọn síbẹ̀.
15 Náómì wí pé, “Wòó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀.”
16 Ṣùgbọ́n Rúùtù dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí o bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ó bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi,
17 Nibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”