17 Nibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”
18 Nígbà tí Náómì rí i wí pé Rúùtù ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́.
19 Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Náómì ni èyí bí?”
20 Náómì sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Náómì. Ẹ pè mí ní Márà (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.
21 Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kíń ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”
22 Báyìí ni Náómì ṣe padà láti Móábù pẹ̀lú Rúùtù, ará Móábù ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.