13 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.
14 Ańgẹ́lì ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbé wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jówú fún Jérúsálẹ́mù àti fún Síónì.
15 Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ: nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú.’
16 “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jérúsálẹ́mù wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jérúsálẹ́mù.’
17 “Má a ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ire kun ilú-ńlà mi ṣíbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Síónì nínú ṣíbẹ̀, yóò sì yan Jérúsálẹ́mù ṣíbẹ̀.’ ”
18 Mo si gbé oju sòkè, mo sì rí, sì kíyèsí i, ìwo mẹ́rin.
19 Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Júdà, Ísírélì, àti Jérúsálẹ́mù ká.”