1 “Ní ọjọ́ náà isun kan yóò sí sílẹ̀ fún ilé Dáfídì àti fún àwọn ará Jérúsálẹ́mù, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.
2 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kọjá kúrò ni ilẹ̀ náà.
3 Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò ṣọtẹ́lẹ̀ ṣíbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè: nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá ṣọtẹ́lẹ̀.
4 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlúkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí ṣọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ.
5 Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’
6 Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’
7 “Díde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi,àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,àwọn àgùntàn a sì túká:èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kékèké.
8 Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
9 Èmi ó sì mú apá kẹ́ta náà la àárin iná,èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán góòlu wò:wọn yóò sì pé orúkọ mi,èmi yóò sì dá wọn lóhùn:èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”